Àyájọ́ Ọjọ́ Àrùn Kògbóògùn

Oun tó bá léni léni tí kò ríni mú, ṣèbí òun ni Ìmúnitì. Àbí? Ilé-aiyé kún fún àìmọye àrùn tí nbá ọmọ ènìà jà. Púpọ̀ nínú àwọn àrùn wọ̀nyí, àwọn kòkòrò tí a kò lè fi ojú lásán rí ni wọ́n nfà wọ́n. Tí kìí bá ṣe fún ìṣẹ̀dá ara ọmọ ènìà ni, a kò lé gbé ilé-aiyé yìí ju ọjọ́ méjì sí mẹ́ta lọ.

Yàtọ̀ sí ògùn tí a nlò láti mú ara wa dá tí ó bá rẹ̀wá, àgọ́ ara wa gan-an kún fún àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n ndáàbò bo ara wa. Àwọn ọmọ-ogun yìí máa nbá àwọn kòkòrò aṣekúpani jà tí wọ́n bá wọnú àgọ́ ara wa. Ìyẹn ni pé wọ́n wà fúnwa gẹ́gẹ́ bí àjẹára ni. Àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan wà nínú ara wa tí iṣẹ́ wọn jẹ́ pípèsè àti dídarí àwọn ọmọ-ogun ara náà. Tí àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí bá kófìrí àwọn kòkòrò aṣekúpani nínú àgọ́ ara, kíákíá ni wọ́n máa da àwọn ọmọ-gun síta kí wọn lọ dojú ìjà ko wọ́n. Nígbà míràn àwọn ògùn tí a nlò dà bí irinṣẹ́ àti nkan ìlò ogun fún àwọn ọmọ-ogun ara wa. Á jẹ́ bí ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti ṣẹ́gun àwọn kòkòrò amúniṣàárẹ̀ tí wọ́n nbá jà.

Àmọ́ kòkòrò ju kòkòrò lọ. Irúfẹ́ kòkòrò aṣekúpani kan wà tí wọ́n npè ní HIV. Tí HIV bá wọnú àgọ́ ara tán, àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n npèsè ọmọ-ogun ara ní í bájà. Díẹ̀ díẹ̀, á máa dín agbára ara ẹni láti dáàbò bo ararẹ̀ kù. Tó bá dínkù dé'bìkan tí kòsí àjẹára fún ènìà mọ́,

wọ́n á ní olúwarẹ̀ ní àrùn Kògbóògù, tí wọ́n npè ní AIDS. Ajẹ́pé ara ẹni kò lè bá nkankan jà mọ́. Àìsàn tí kò tó nkan ní í ránni lọ s'álákeji. Ìyẹn ni pé AIDS fúnrarẹ̀ kọ́ ni nsẹkú pani, bí kìí ṣe ìyà nlá tó gbéni ṣánlẹ̀, tí kékèké wá ngorí ẹni. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún fẹ́ ṣe bí òwe.

Akitiyan nlá ni àwọn onímọ̀ iṣègùn àti oníwàdìí-jinlẹ̀ ilera ti ṣe káàkiri àgbáyé láti wá ògùn tó kápá àrùn yìí. Ìlọsíwájú sì ti wà dájú-dájú, ṣùgbọ́n kò tíì sí àwárí kankan tó kápá àrùn kògbóògùn pátápátá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìà ló sì ti ti ipasẹ̀ àrùn yìí rè'wàlẹ̀àsà.

Ní ọdún 1988 wọ́n dá ọjọ́ kíní ọsù Ọpẹ sí gẹ́gẹ́ bíi Ọjọ́ Àrùn Kògbóògù Àgbáíyé. Nkan mẹ́ta ni ọjọ́ náà wà fún.

1. Ìrántí àwọn tí wọ́n ti di olóògbé nípasẹ̀ àrùn Kògbóògun, àti àwọn tí wọ́n ngbé pẹ̀lú kòkòrò àrùn náà nínú ara wọn.

2. Ìfihàn àtìlẹ́hìn àti ìbásowọ́pọ̀ àti ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan àwọn tí wọ́n nṣe ìwádìí tó jẹmọ́ àrùn Kògbóògùn.

3. Láti ṣe ìtànká ìmọ̀ nípa àrùn Kògbóògùn, àti láti ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo gbòò nípa àrùn náà.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!