Àwọn ọmọdé kú ikú ìbọn :'(
Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan ló ṣẹlẹ̀ ní ìlú Newton ní ìpínlẹ̀ Connecticut ní àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì tó kọjá o. Orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ni ìpínlẹ̀ náà wà.
Ọkùnrin ọmọ ogún ọdún kan ló gbé ìbọn ìyá rẹ̀, tó sì yin ìyá rẹ̀ pa nínú ilé wọn. Lẹ́hìn èyí ló tún gbéra o kọrí sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ìyá rẹ̀ ti jẹ́ olùkọ́. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìyá rẹ̀ ló wà débẹ̀, ó sì kó ibọn oríṣìí mẹ́ta dání. Ìlé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí njẹ́ Sandy Hook ni ọkùrin aṣebi yìí ti da ìbọn bo àwọn ọmọdé kékèké tí ọjọ́-orí wọn jẹ́ mẹ́fà àti méje. Ogún ọmọdé ni wọ́n kú ikú oró lọ́wọ́ ìkà ọkùnrin lọ́jọ́ náà. Kò bá jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn olùkọ́ ti wọn ṣe takun-takun làálàá láti dáàbò bo àwọn ọmọdé. Àwọn tí wọ́n ráàyè sá àsálà fún ẹ̀mí wọn sá síta kíákíá kúro nínú ewu ìbọn náà. Bẹ́ẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn olùkọ́ náà ni wọn fara gbọta. Àwọn olùkọ́ mẹ́fà ni wọn sì gba ibẹ̀ ṣaláìsí.
Isẹ́jú mẹ́wàá péré lo kọjá ti àwọn ọlọ́pàá fi dé tìbọn-tìbọn, ṣùgbọ́n eléyìí ti pẹ́ jù. Ọkùnrin náà ti pa púpọ̀ núnú àwọn ọmọdé àti àgbà, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ léṣe. Àti pé ó kanlẹ̀ ti kọjú ìbọn sírarẹ̀, ó ti dágbére sí ilé-ayé kí àwọn agbófinró tó dé.
Ìbànújẹ́ nlá ni eléyìí jẹ́ fún gbogbo ará ìlú àti gbogbo Amẹrika lápapọ̀. Ààrẹ Obama ti ṣe ìkéde nípà ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wípé ọ̀rọ̀ yí ba òun nínú jẹ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ̀ Amẹrika, àti gẹ́gẹ́ bíi baba ọmọ méjì fúnra òun. Omi fẹ́ máa bọ́ lójú rẹ̀ bí ó ṣe nṣe ìkéde náà.
Ìwádìí ìjìnlẹ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ báyìí láti rí kíló lè fa kí ọkùnrin apààyàn náà kọjú ìbọn sí àwọn ọmọdé tí wọ́n kéré báyìí. Àti pé irúfẹ́ àwọn ìbọn tó lò mú kó lè pààyàn kíákíá nítorí àwọn ìbọn alágbára ni ó lò. Àwọn ìbọn náà sì gba ọgbọ̀n ọta lẹ́ẹ̀kannáà.
Òfin Amẹrika gbàá láàyè fún ẹnikẹ́ni láti ní ìbọn. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ìyá ọkùnrin apànìyàn náà fi ní ìbọn nílé, tí ọwọ́ ọmọ rẹ̀ fi tẹ̀ẹ́. Àwọn olóṣèlú kọ̀ọ̀kan ti fipá mú ààrẹ Obama pé kó tiraka láti yí òfin náà pádà, kí wọ́n fi lè dẹ́kun àwọn íṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí nítorí kìí ṣe àkọ́kọ́ rẹ̀ nìyí. Ṣùgbọ́n á ṣòro fún Obama nítorí pé àwọn olóṣèlú míràn gbàgbọ́ pé ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Amẹrika ni láti ní ìbọn. Wọ́n ní bí àwọn babánlá àwọn tó tẹ ilẹ̀ Amẹrika dó ṣe fẹ́ ẹ nìyẹn. Àmọ́ àwọn ìdàkejì wí pé láyé àtijọ́, kò tíì sí àwọn ìbọn alágbára ti òde òni.
Gbogbo àgbáyé ló bá Orilẹ̀èdè Amẹrika kẹ́dùn. Iṣẹ̀lẹ̀ burúkú gbáà lo ṣẹlẹ̀ yìí. Kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ àwọn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn. Kí Olódùmarè má jẹ́ káa rí irú èyí mọ́ láíláí.

Comments
Post a Comment