Àwọn Omi Sulis

Ẹni tó wípé Alákọ̀wé ìwọ dà láti'jọ́ yìí? Ó mà ṣe fírífírí kẹ̀. Enítọ̀hún ṣeun aájò wa jàre. Àṣá ò pẹ́ lóko bẹ́ẹ̀ rí ọ̀nà ló pọ̀

Ìrìnàjò mà ni Alákọ̀wé tẹsẹ̀ bọ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan o. Mo dé ìhà ìlà-oòrùn àgbáyé níbi tí ọjọ́ ti ń kọ́kọ́ mọ́n. Mo dé ìwọ̀-oòrùn níbi tí agbami òkun ti lọ kánrin-kése kọ́já ibi ojú rí. Àní mo dé àríwá ayé níbi yìnyín gbé rọ̀ dàálẹ̀ bí òjò. Gúsù ńkọ́? Níbi oòrùn ti ń yọ lóru gànjọ́, gbogbo rẹ̀ ló sojú èmi kinní yìí.

Ìlé-ayé yìí kún fún nkan àdìtú àti ìyanu. Ìrìn gbé mi dé ìlú kan tí ń jẹ́ Bath. Orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ìlú náà wà.



Nkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ṣẹ́hìn ni wọ́n tẹ ìlú náà dó sí etí odò Avon. Àwọn ará Róòmù tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ dó sọ ọ́ lórúkọ 'Aquae Sulis' (Àwọn Omi Sulis). Òrìṣà ayé-àtijọ́ kan nílẹ̀ yìí ni ó ń jẹ́ Sulis. Àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n wà níbẹ̀ kí àwọn Gẹ̀ẹ́sì tó dé ni wọ́n ń bọ òrìṣà náà nígbà náà.





Ìdí tí wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Aquae Sulis ni pé sẹ́lẹ̀ru omi gbígbóná kan wà níbẹ̀ tí wọ́n gbàgbọ́ pé a máa wo aláìsàn sàn, a sì máa múni lára dá. Nítorí náà àwọn ará Róòmù kọ́ ilé-ìwẹ̀ ńlá kàbìtì yí àwọn sẹ́lẹ̀ru náà po. Ìlé ọ̀hún wá dúró gẹ́gẹ́ bí ilé ìwòsàn àti ìgbafẹ́ ọlọ́kanòjọ̀kan fún àwọn arawọn, àti àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́lá.





Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, òkìkí Aquae Sulis kàn káàkiri gbogbo ìlẹ̀ Róòmù ìgbà náà. Ṣé ìjọba amúnisìn ni Róòmù jẹ́ nígbà náà, a jẹ́ pé títí dé ilẹ̀ Ígíbíìtì àti India ni òkìkí rẹ̀ kàn dé. Àsìkò yìí ni ìgbà tí Jésù wà ní ilé-ayé. Nígbà náà kò sí ibi aláìsàn ò kí ń wá ìwòsàn dé. Káàkàkiiri àgbáyé ni àwọn ènìyàn ti rin ìrìnkèrindò dé Aquae Sulis pé kí àwọn lè rí ìwòsàn.

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ láyé-àtijọ́ tún fún àwọn èèyàn ìgbà náà ní ìdánilójú pé agbára Sulis ń bẹ nínú omi náà. Olorì Gẹ̀ẹ́sì kan tí kò rí ọmọ bí lọ síbẹ̀, ó sì wẹ̀ nínú omi Sulis. Ló bá di igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí í gb'ódò tí Yoòbá ní kìí y'àgàn. Wẹ́rẹ́, olorì finú ṣoyún, ó sọ̀ láyọ̀.




Nígbà tó yá ni ìlú ọ̀hún gbòòrò dé bó ti rí. Ìjọba Róòmù kásẹ̀ nílẹ̀ káàkiiri àyé, àwọn Gẹ̀ẹ́sì gba àkóso ìlú náà, wọ́n sì yí i lórúkọ padà sí Bath.  Lóde òní, Bath jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì ní orílẹ̀ UK. Ẹní bá ṣe àbẹ̀wò dé UK, kí enítọ̀hún yáa gbìyàjú dé ìlú Bath. Ẹ ó ríran wò!




Wọ́n ní tí ẹ bá dé ibi sẹ́lẹ̀ru Sulis, tí ẹ ju owó sínú ẹ̀, ẹ di olóríire nìyẹn.  Èyí ló ká ẹlòmíràn lára tó fi ju odidi pọ́ùn kan sínú omi.  Ṣé mákọjá mi Olùgbàlà kìí ṣe orin àkúnlẹ̀kọ àbí? Òun ló dífá fún Alákọ̀wé ní ìlú Bath, tó ju pọ́ùn méjì sínú omi.  Àpèmọ́nraẹni là á pe tèmídire :)

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?