Arúgbó atọrọjẹ òyìnbó bọ̀ ó pòwe

Arúgbó òyìnbó bọ̀ ó pòwe. Ó ní "bí iṣu ẹni bá ta àá fọwọ́ bòójẹ ni"! Èèbó káàbọ̀.
Ọ̀rọ̀ kànkà yí wáíyé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan fẹ́ pàdé láàrin ìlú. Ọ̀rẹ́ mi náà ló pẹ́ díẹ̀ kó tó dé ti mo fi lọ́ dúró dèé ní Starbucks kan tí nbẹ lẹ́bàá ibi tí a fìpàdé sí. Nínú gbogbo onírúirú nkan mímu tí wọ́n ntà níbẹ̀, frapuccinno ni mo yàn nítorí ooru mú díẹ̀ lọ́jọ́ náà. Frapuccinno yìí, omi-dídì ni wọ́n fi nṣe é. Wọ́n á lọ̀ọ́ kúnná, wọ́n á wá da Kọfí lùú, wọ́n a wá pòó pọ̀ dáadáa nínu ẹ̀rọ ọlọ. Gbogbo ẹ̀ á wá tutù nini. Ìtura gbáà ló jẹ́ nígbà ooru.

Ní ìta gbangba ibi wọ́n to àga sí fún àwa oníbàárà wọn ni mo fìkàlẹ̀ lé o. Mo ti agbórinsétí bọ̀ ẹtí, mo yín ọrin aládùn síi lóri iPhone mi, kí afẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní kẹlẹwu. Atẹ́gùn àlàáfíà kan náà bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́. Mo bá fẹ̀ pẹrẹgẹdẹ sórí àga mo fẹ̀hìntì dáadáa. Mo kọ̀wé ranṣẹ́ sí ọrẹ́ mi sórí alágbèéká rẹ̀ pé kó wá bámi níbẹ̀ tó bá dé.

Bí mo ṣe fẹ́ máà bá ìgbádùn mi lọ ni mo fura pé ẹnìkan nbẹ lẹ́hìn mi. Wéré ni mo bá bojú wẹ̀hìn. Mo rí ìyá arúgbó òyìnbó kan tó nsọ̀rọ̀ kan sí mi, ṣùgbọ́n tí ng kò gbọ́ nkan tó nsọ nítorí kiní orin tí mo tì bọ'tí. Mo bá yọ ọ́ létí kí ng fi lè gbọ́'hun tí arúgbó nwí. Àṣé ìyá yìí ntọọrọ owó ni. Ó ní kí ng jọ̀ọ́ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún òun kí òun lè rí oúnjẹ jẹ. Ah! Àánú arúgbó náà ṣe mí púpọ̀. Iye owó tó tọọrọ kò tó ìdajì owo frapuccinno tí mo gbé síwájú mi.

Mo bá tọwọ́ b'àpò mo kó gbogbo owó tí nbẹ níbẹ̀ fún arúgbó yìí. Kìí ṣe owó bàbàrà lọ títí o, àmọ́ ó jọ̀ọ́ lójú púpọ̀ púpọ̀. Ìyá arúgbó òyìnbó bá dúpẹ́ dúpẹ́. Ó wí pé ó ya òun lẹ́nu gidi pé mo fún òun lówó. Àti pé ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Èmi sọ fún un pé kò tọ́pẹ́ rárá. Pé kó yáa sáré lọ wá nkan jẹ, kí òyì má kọ́ọ kó má dàákú síwa lọ́rùn o. Ìgbà náà ló bá nawọ́ sí àwọn kan tọ́n jòkó lókèrè. Ó wípé ọ̀dọ̀ wọn lòun ti kọ́kọ́ tọọrọ owó, ṣùgbọ́n wọn kò fún òun ní nkankan rara. Kódà wọ́n lé òun dànù ni. Àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan ni. Wọ́n n fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀. Wọn kó owó iyebíye kalẹ̀ wọ́n npín-in láàrin arawọn. Gbogbo nkan tí wọ́n nsọ ni gbogbo aráyé ngbọ́ pátápátá. Ó dàbí pé iṣẹ́ òwò kan tí wọn sẹ ni wọ́n ti jèrè rẹpẹtẹ, ti wọ́n fi nyọ̀ bẹ́ẹ̀.

Àkókò yìí ni àgbàlagbà òyìnbó bá mín kànlẹ̀, ó sọ̀rọ̀ àgbà. Ó wípé ọjọ́ ti pẹ́ tí òun ti wà ládùúgbò náà. Òun sì mọ bí nkan ṣe rí. Ó wípé àwọn jàgùdà pọ̀ láàrin yẹn tí wọ́n wá nkan tí wọ́n máa jígbé. Pé kò ní yà òun lẹ́nu tí àwọn jàgùdà olè bá tẹ̀lé àwọn ọkùnrin náà láti jàwọ́n lólè, tí wọ́n á sì gba gbogbo owó ọwọ́ wọn. Ó bá tún dúpẹ́ lọ́wọ́ mi lẹ́ẹ̀kan síi, kó tó máa rọra rìn lọ.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!