Alakowe.com Pààrọ̀ ẹ̀wù

Ẹ pẹ̀lẹ́ o ẹ̀yin èèyàn mi.  Ó mà tó'jọ́ mẹ́ta kan tí mo ti kọ nkan síbí.  Àṣá ò pẹ́ lóko bẹ́ẹ̀ rí o, ọ̀nà ló jìn. Ṣẹ́ẹ̀ bínú?

Pèrègún tí ń bẹ lódò kìí kú. Ọdọọdún ló ń yọ àwọ̀ tuntun.  A díá fún alakowe.com tó pààrọ̀ ẹ̀wù. Bẹ́ẹ̀ ni o, a ti pa aṣọ aláwọ̀-ewé èsí tì, a gbé aṣọ àlà funfun báláú bọra.
Ṣé ó wuyì àbí kò wuyì? Ó dára àbí kò dára?  Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ o :)

Àyípadà míràn ni pé màá máa fi àwọn àwòrán tí mo ń yà hàn níbí.  Ṣé mo ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ayàwòrán ni mí. Òwe Gẹ̀ẹ́sì kan a sì máa wí pé àwòrán kan ṣoṣo a máa fọ ẹgbẹ̀rún gbólóhùn.  Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni.

Toò, wọ́n ní oun tó bá yá kìí tún pẹ́. Ẹgbà'yí ẹ tọ́ ọ wò.  Ìlú Èkó rèé arómisá lẹ̀gbẹ-lẹ̀gbẹ.






Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!