Àjọ̀dún #YAF

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ìyẹn Àbámẹ́ta àti Àìkú ọjọ́ 27 àti 28 oṣù yí, gọngọ sọ ní agbègbè Hackney. Ayẹyẹ àṣà ọnà Yorùbá ló ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Clissold fún ọjọ́ méjì gbáko. Ọdún kẹẹ̀rin tí àjọ̀dún náà ṣẹlẹ̀ rèé. Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àjọyọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oòjíire ni, àti àwọn ti ibi tí àṣà wa tàn dé káàkiri àgbáyé bíi Brasil àti Kuba.

Ọrísìírírìí ni wọ́n ṣe létò, àmọ́ èyí tó pabambarì ni Batala tí í ṣe ẹgbẹ́ onílù. Orílẹ̀èdè Ígílándì ni wọ́n ti wá àmọ́ irúfẹ́ ìlù tí wọ́n lù, Brasil ni àṣà ọ̀hún ti jẹyọ.

N kò bá kọ jù báyìí lọ, àmọ́ kíní ọ̀hún ò tiẹ̀ wúni lórí lọ títí o jàre. Àwọn olóòtú ètò gbìyàjú pé kí ayẹyẹ ọ̀hún ó l'árinrin, àmọ́ àwọn èèyàn wa ò kọbiara sí i. Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn èèyàn wa tí wọ́n fi ìlú Lọndọn ṣe ibùgbé pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní, pàápàá ní agbègbè Hackney gan-an, àwọn ọmọ Yoòbá tó yọjú síbẹ̀ lè má ju mẹ́wàá lọ. Ṣé ẹ mọ̀ pé nkan tiwa ò kí ń jọ wá lójú lọ lo títí. Kání òṣèré Amẹ́ríkà kan ló yọjú sí agbègbè náà báun, ọgbà náà ò bá kún dẹ́mú-dẹ́mú ni. Kí Edùmàrè ko wa yọ.

Nkan kejì tó kù díẹ̀ káàtó ni pé àwọn àwo orin tí wọ́n lù, àsán azonto ni. Èmi ò fi etí mi gbọ́ orin Yoòbá ẹyọkan ṣoṣo níbẹ̀ o. Kí ló dé? Yoòbá ni ọba ìlù, àwa ni ọba gbogbo orin.

Ìgbà tó ṣe díẹ̀ ni òjò bá bẹ̀rẹ̀, tí àrá ń sán fààràrà. Èmi lérò pé bóyá Olúkòso ń bínú ni. Àrẹ̀mú ò gbọ́ ìlù bàtá kankan, ló bá rọ̀jò lé kiní ọ̀hún jàre. Ni olúkálukú wá sá bọ́ sábẹ́ àwọn ìsọ̀ olónjẹ.

Mo jẹ súyà. Mo jẹ àsáró. Mo tún fi omi tútù lé e. Mo rìn káàkiri àwọn ìsọ̀ aláṣọ kọ̀ọ̀kan. Ìgbà tó yá tó dàbí ẹni pé wọn fẹ́ fi azonto di olúwarẹ̀ létí, ni mo bá kọrí'lé ní tèmi o jàre. Ìyókù tún di ọdún tí ń bọ̀, kí Ẹlẹ́mìí ó má gbà á.
 

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!