Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí

Lónìí òpin ọdún 2012, tí a bá bojú wẹ̀hìn, a ó rí i pé ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ lọ́dúnnìí, tí ilẹ̀ sì fi mu. Oríṣìíríṣìí nkan olókìkí ló ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria àti ni gbogbo àgbáyé. Àwọn nkan rere àti àwọn nkan búburú pẹ̀lú. Ọdún 2012 ni ìdíje Olympics wáyé ní ìlú Lọndon. Ọdún yìí náà ni wọ́n tún Obama yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹrika. Àwọn ìròhìn ayọ̀ oníkanòjọ̀kan náà la gbọ́ káàkiri àgbáyé.

Àmọ́ o, bí ó ti ntutù níbìkan ní í gbóná ní ibòmíràn. Àìmọye jàmbá la gbọ́ pé ó ṣelẹ̀ káàkiri àgbáyé lọ́dúnnìí. Ẹnìkan ló fi ikú ìbọn rán àwọn ọmọdé kékeré lọ sọ́run òjijì ní Amẹrika ni ìjọ́sí. Bẹ́ẹ̀náàni ààrẹ orílẹ̀ Síríà kò dáwọ́ pípa àwọm ọmọ ìlú rẹ̀ dúró. Àwọn ìjì nlá-nlá tún jà káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá lọ́. Ní Naija, ọkọ̀ òfurufú kò yéé jábọ́. Àwọn òlóṣèlú oníwàìbàjẹ́ ò yéé hùwà wọn. Àmọ́n èyí tó kanni lóminú jù ni ti àwọn alákatakítí Boko Haram, tí wọ́n ndúnbú ọmọ ènìyan bí eran lásán.

Ṣùgbọ́n ìrírí ayọ̀ ni tiwa ní ilẹ̀ Yorùbá ni ti ẹlẹ́sìn dé o. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹlẹ́sìn Kiristẹ́nì àti Mùsùlùmí kìí bárawọn ṣe dáadáa ní gbogbo ibòmíràn, irẹ́pọ̀ gidi ló wà láàrin àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì ní ilẹ̀ Káàárọ̀-oòjíire. Kò ṣọ̀wọ́n ká rí ṣóòṣì àti mọ́ṣáláṣí tí wọ́n kọ́ si ẹ̀gbẹ́ arawọn. Ka rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ to já èrò sílẹ̀, kí lágbájá kọrí sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ ké alelúyà, ki tẹ̀mẹ̀dù náà sì gba mọ́ṣáláṣí lọ rèé ké láìláà. Bó ti rí gẹ́lẹ́ ní ilẹ̀ Yoòbá nìyẹn láìsí ìjà, láìsí rògbòdìyàn.

Ní ọdún 2013 tó wọlé dé yìí, aríkọ́ṣe àti àwòkọ́ṣe ni ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ fún gbogbo àgbáyé nípa ìrẹ́pọ̀ èsìn. "Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí o...." Kí gbogbo wa káàkiri àgbáyé jáwọ́ nínú ìwa ẹlẹ́sìnmẹ̀sìn tó nkó jambá nlá ba ilé-ayé yìí. Ọlọ́run níkan ló mọ ẹni tí ó là o.

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!