Àgùntàn aláìníṣòro ẹ̀dá
Nínú gbogbo ẹranko tí nbẹ lórí aiyé, àgùntàn lá dá lọ́la jùlọ. Kò sí ẹja náà nínú omi kómi, tàbí ẹiyẹ kankan yálà èyí tí nfò lókè ni tàbí èyí tí nfẹsẹ̀ méjì rìn nílẹ̀, tí a dá lọ́la bí àgùntàn.
Àgùntàn jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ gbáà. Kódà ìwà àgùntàn dára tó bẹ́ẹ̀ dé ibi pé àìmọyé ọlọgbọ́n ni wọ́n fi ṣe àpèjúwèé ìwà rere. Ìwà tí àwa ọmọ ènìà gan-an alára yẹ ká fi ṣe àwòkọ́ṣe. Ọmọ ènìà ò bá hùwà pẹ̀lé bí àgùntàn, àláfíà ò bá tàn kárí gbogbo aiyé jákè jádò.
Bíótilẹ̀ jẹ́pé àsìnjẹ ọmọ ènìà ni púpọ̀-jùlọ nínú àwọn àgùntàn jẹ́, eléyìí kò búrú fún wọn rárá. Ní gbogbo ọjọ́ aiyé wọ́n, bíbọ́ ni wọ́n bọ́ wọn bi ọmọ tuntun. Àgùntàn kan kìí ṣe aláìní l'áíyé n'bí! Wọ́n a jí, wọ́n a jẹun, wọ́n a ṣeré, wọ́n á sùn. Ogun kan ì báà máa jà níbìkan. Jàmbá nlá kan ì báà máa ṣẹlè níbìkan. Kò kúkú sí nkan tó kan àgùntàn níbẹ̀.
Àní kì báà jẹ́pé lóòótọ́ èrò ìsásùn l'agbárí wọ́n nṣẹ, àgunlá àgùntàn. Àti pé ìwù ara wọ́n á di aṣọ lára ọmọ ènìà lọ́jọ́ iwájú, àguntẹ̀tẹ̀. Bí àgùntàn bá ti rí koríko jẹ, tí ó r'ómi mu, àbùṣé bùṣe. Èwo làbùrọ̀ ronú? Ṣèbí kò sí ẹni tí ò ní kú?
Wọ́n ní ìwà lẹwà ọmọ ènìà. Ní ìwọ̀n ìgbà tó jẹ́ wípé ẹlẹ́ran ara ni àgùntàn nṣe, a jẹ́pé ìwà lẹwà ọmọ àgùntàn náà. Bíótilẹ̀ jẹ́pé àgùntàn ya òmùgọ̀ lójú àwa ọmọ ènìà, aṣáájú ni wọ́n jẹ́ nípa ìwà.
Nlẹ́ o ìwọ àgùntàn aláìníṣòro ẹ̀dá. Ìwọ rọra dùbúlẹ̀ lóri pápá koríko tútù kí o máa gbádùn lọ o jàre!

Comments
Post a Comment