Àgbò Iléyá

Orí yéye ní mògún, t'àìṣẹ̀ ló pọ̀. A díá fún àgbò tó di ẹran Iléyá.

Ẹ gbọ́ o. Ọ̀ràn kí ni àgbò dá tó fi jẹ́ pé ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún mùsùlùmí ń yọ ọ̀bẹ́ sí i lọ́rùn?

Láyé àtijọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ọkùnrin kan ń bẹ nígbà náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ibrahim. Ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo ni arákùnrin náà bí. Ó sì pẹ́ kí ó tó ríi bí. Ibrahim jẹ́ ẹnìkan tó ní ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run gidi gaan ni. Ó wí pé kòsí nkan náà tí Ọlọ́run fẹ́ tí òun kò ní ṣe.

Ọjọ́ kan dé tí Olódùmarè dán Ibrahim wò. Ó wí fún un pé kó fi àrẹ̀mọ rẹ̀ rúbọ sí Òun. Ìyẹn Ishmael, tí í ṣe ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo. Láìsí àní-àní kankan, Ibrahim pe Ishmael kó nìṣó. Ishmael náà ní ìtẹríba fún Ọlọ́run àti fún bàbá rẹ̀. Òun náà kò ṣiyè méjì, ó gbéra ó tẹ̀lé bàbá rẹ̀. Nígbà tí Ibrahim ṣetán láti pa ọmọ rẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ, tó gbọ́wọ́ idà sókè ni Ọlọ́run fi ọmọ àgùntàn ránṣẹ́ láti fi rọ́pò ọmọ ènìà.

Ènìyàn pàtàkì gbáà ni Ibrahim jẹ́ lórí orílẹ̀ ayé yìí. Ànábì Ọlọ́run ni àwọn ẹlẹ́sìn Islam kàá kún. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ fún àwọn Kìrìstẹ́nì àti àwọn Júù (Yawúdí) pẹ̀lú. Kódà, ọmọ Ibrahim tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isaac ni babańlá àwọn ẹ̀yà Isreal àti Juda. Àríyànjiyàn kan nbẹ nínú ìyàtọ̀ tó wà nínú ìtàn yìí. Àwọn Kìrìstẹ́nì àti Júù wí pé ọmọ Ibrahim kejì Isaac ni Ọlọ́run ní kó fi rúbọ sí Òun.

Ìdí ẹ̀ rèé tó fi jẹ́ pé àwọn mùsùlùmí a máa pa ẹran àgbò ní àjọ̀dún yìí tí orúkọ rẹ̀ ń ṣe Eid al-Adha ní èdè Lárúbáwá. Ìléyá ni wọ́n ń pè é ní èdè Yorùbá nítorí pé nígbàtí àgùntàn ti rọ́pò ènìà lójúbọ, Ibrahim wí fún Ishmael pé iléyá!

Comments

Popular posts from this blog

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Etí òkun ìgbafẹ́

Mojúbà o!