Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè


Njẹ́ ibi orí dáni sí làá gbé. Ibi orí ranni lọ làá lọ. Bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ori ránni làá ṣe. Èyí ló fa máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ gbogbo ẹ̀dá. Iṣé òòjọ́ wọn ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀nà àti là yìí náà ni wọ́n ń lépa.

Máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ yìí a máa sú ọ̀pọ̀lọpọ̀ dé'bi pé wọn kìí kíyèsí nkan lọ titi lọ́nà ibi tí wọ́n ń lọ. Kí wọ́n ṣáà tètè dé ibiṣẹ́, kí wọ́n tètè parí iṣẹ́, kí wọ́n sì tètè padà dé'lé ló jẹ wọ́n lógún.

Bí i tẹ̀mi Alákọ̀wé kọ́. Ní tèmi o, mo máa ń ṣí ojú mi kalẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà ni. Mo sì máa ń ṣe àkíyèsí gbogbo oun tí ń lọ ní àyíká mi. Èmi a máa rí àwọn nkan ìyanu káàkiri gbogbo ilẹ̀ tí mò ń tẹ̀, èmi a sì máa gbé orúkọ́ Ọlọ́run ga. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, n a máa rí ẹwà nínú àwọn nkan kékèké tí àwọn míràn ò kà kún nkankan. Ṣé bó ti wu Elédùà ló ń ṣ'ọlá ẹ̀? Ọba mi a ṣèkan bí àpáta gbànyàyà, Ọba kannáà yìí a ṣe òmíràn bí ọ̀kúta wẹwẹ tí ń bẹ nínú erùpẹ̀.

Èdùmàrè yìí tún ṣe iṣẹ́ ẹ̀ l'áṣepé, ó fi làákáyè jíìnkí ọmọ ẹ̀dá. Ó ní ká máa fi ọgbọ́n orí wa dárà ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Irúfẹ́ àrà náà ni mo mà máa ń rí lọ́nà ibiṣẹ́ o. Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè ni nkan náà. Bíótilẹ̀jẹ́pé gbogbo èèyan tí wọ́n ń kọjá níbẹ̀ ò tilẹ̀ kíyè sí i, tàbí kí wọ́n rí i ṣùgbọ́n kí wọ́n má kà á kún nkankan. Àmọ́ èmi Alákọ̀wé, nkan arẹwà gbáà ni mo kà á kún. Tó fi jẹ́ pé mo mọ̀ńmọ̀ ya àwòrán rẹ̀ fún ayé rí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó lágbára jù, kí iyì àwọ̀ rẹ̀ lè hàn dáadáa. Ọ̀rọ̀ yìí á ti yé àwọn afẹ̀rọyàwòrán ẹgbẹ́ mi.

Ẹ̀yin náà ẹ wò ó. Njẹ́ ọ̀dà tí wọ́n kun àgádágodo yìí rẹwà àbí kò rẹwà? Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ èsì yín o.

Comments

Popular posts from this blog

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Kíni ìtumọ̀ "SIM Card" l’édè Yorùbá?

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn