Yoòbá ní "Aiyé nyí lọ biri-biri bí òkúta". Àṣé ìtunmọ̀ nbẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí ju bí a ṣe rò lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀jìnlẹ̀ ti fi yé wa pé ọ̀bìrìkìtì ni ilé-aiyé nṣe, kìí ṣe pẹlẹbẹ. Bí ilé-aiyé ṣe tóbi tó, àti bí àwa ọmọ ènìà ṣe kéré síi to, ló fi dà bẹ́ẹ̀ lójú tiwa. Àti pé ilé-aiyé yìí ò dúró lójú kan rárá. Nṣe ló nyí birir bí òkòtó. Ó sì tún npòòyì yí òòrùn po. Ìyíbiri ẹyo kan ló nfúnwa ni ẹyọ ọjọ́ kan. Nítorí pé ihà ilé-aiyé kan ló kojú sóòrùn lẹ́ẹ̀kannáà, tí ìdàkejì á sì kọjú sí òkùnkùn òfurufú, ìmọ́lẹ̀ òòrùn yìí ni a npè ní ojúmọ, tí òkùnkùn ṣì njẹ́ àsìkò alẹ́ àti òru. Wákàtí mẹ́rìnlélógún ni ilé-aiyé fi nyí biri lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, èyí tí nṣe ọjọ́ kan. Nítorí ilé-aiyé dàbí ọ̀bìrìkì, o yẹ́ kí iye wákàtí tí ihà a rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fi kọjú sóòrùn jẹ́ méjìlá, kó sì kọ́ju sókùnkùn fú iye wákàtí kannáà. 12 + 12 = 24. Ìyẹn ni pé kí ojúmọ́ àti ilẹ̀ṣú jẹ́ dọ́gba-dọ́gba. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní ihà àríwá ilé-aiyé àti ihà gùsù aiyé pẹ̀lú, ọjọ́ ò dọ́gba rara. Ìdí èyí ni pé ...
Comments
Post a Comment