Posts

Showing posts with the label Yoruba

Computer kìí ṣẹ Ayárabíàṣá

Image
Ó dáa ó dáa! Mo mọ̀n pé ẹ̀rọ ayárabíàṣá lorúkọ tí computer ń jẹ́ ní èdè Yorùbá. N kò jiyàn rẹ̀ rárá o. Dájúdájú gbogbo wa la ti gbà pé orúkọ rẹ̀ nìyen. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá fojú inú wòó, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe ní alẹ́ ọjọ́ kan, ẹ ó ríi pé orúkọ yìí kù díẹ̀ káà tó! Ní alẹ́ ọjọ́ tí mo ń sọ yìí, mo tan ẹ̀rọ ayárabíàṣá mi pé kí n sáré ṣiṣẹ́ kan kíakiá kí n tó lọ sùn. Títàn tí mo tàn án tán, lóbá dí kùùrùrù, ó di kẹẹrẹrẹ. Bí ó ti ń sún kẹrẹ ni ó ń fà kẹrẹ. Nǹkan tí kò gbà ju ìsẹ́jú kan lọ tẹ́lẹ̀, ó di oun tí a ń fi ìsẹ́jú mẹ́rin ṣe. Gbogbo ẹ̀ wá ń fẹsẹ̀ falẹ̀ bí ìjàpá. Ẹ̀rọ wá di ẹ̀rọ àfìdíwọ́bíìgbín! Àb’ẹ́ẹ̀ríǹkan? ǹjẹ́ orúkọ yìí péye mọ́n? Ótì o, èmi ò rò bẹ́ẹ̀ rárá. Nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nipé lẹ́hìn bíi ọdún méjì láti ìgbà tí ènìà bá kọ́kọ́ ra ẹ̀rọ ní títun, ẹ̀rọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́. Àwọn nǹkan inú ẹ̀rọ tí wọ́n ń mú u ṣiṣẹ́ náà a máa gbó pẹ̀lú. Àmọ́ pàápàá jùlọ, nǹkan tó fàá nipé bí àsìkò àti ìgbà ṣe ń lọ síwájú ni iṣẹ́ tí a ń fún ẹ̀rọ yìí ṣe ń ṣòro síi tí ó sì ń wúwo síi...

Bàtà Àràmàndà

Image
Abẹsẹ̀ gígùn mà wá dáràn o! Ẹ ní kílódé? Yó dáa fún yín! Ṣèbí tí èyàn bá ń wá ìbọ̀sẹ̀ tàbí sòkòtò rà, èyí tó bá gùn délẹ̀ tàbí èyí to wọ̀’yàn lẹ́sẹ̀ l’èyàn ń wá? Àyàfi tí irúfẹ́ oge kan bá gbòde tójẹ́pé ṣòkòtò-ò-balẹ̀ l’olúwarẹ̀ ń kúkú wá ká. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣòkòtò ó gbọdọ̀ gùn délẹ̀ ni. Ó sì yẹ kí ààyè ó gba esè nínú u bàtà pẹ̀lú. Ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọnsẹ̀ àwọ́n géndé, láìí ṣe t’ọmọdé, máa ń ṣábàá bẹ̀rẹ̀ láti 7 dé 12, ìyen fún génde ọkùnrin. Ìgbàmíràn èyàn tún lè rí 6 fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ kékeré, tàbí 13 (tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ) fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ gòdògbà. Tí géndé ọkùnrin mẹ́wàá bá wọn ẹsẹ̀, mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án nínu wọn ni wọ́n á bọ́sí láti 7 dé 10. Nítorí èyí ni àwọn onísọ̀ ibọ̀sẹ̀ dín iye bàtà tó ju 10 lọ kù. Báyìí, wọ́n a le rí bàtà tà dáadáa síi, nítorípé díẹ̀ náà ni iye àwọn oníbàárà wọ́n tí ẹsẹ̀ ẹ wọ́n ju 10 lọ. Nǹkan tó fa wàhálà fún ẹlẹ́sẹ̀ ńlá rèé o! Olúwa rẹ̀ ó wá pàráàró títí yó fi sú u. Tí ẹni ọ̀hún tún bá ṣoríire tó rí ibọ̀sẹ̀ tó bẹ́sẹ̀ ẹ rẹ̀ mu, bàtà ńlá yìí...