Posts

Showing posts with the label United Kingdom

Elizabeth ti lo ọgọ́ta ọdún lórí oyè

Image
Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kaàrún ọdú un 1953 ni Elizabeth gorí oyè. Ó wa jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba orílẹ̀èdè UK àti gbogbo àwọn ilú káàkiri àgbáyé tí wọ́n wà lábẹ́ UK nítorí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ló mú wọn sìn. Orílẹ̀èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣùgbọ́n òmìnira dé fún wa ní ọdún un 1960, a sì kúrò lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ní ọjọ́ àyájọ́ ọdúnìí tó pé ọgọ́ta ọdún tí Elizabth gorí oyè, àkànṣe ńlá gidi ló jẹ́. Ọjọ́ márùn-ún gbáko ni wọ́n fi ṣe ètò ẹ̀yẹ yìí. Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì dá ọjọ́ Ìṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsimin fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n ó le r’áàyè lọ wòran níbi ayẹyẹ nlá yìí. Ṣé ọjọ́ Ajé kúkú ti jẹ́ ọjọ́ odún kan tẹ́lẹ̀, gbogbo ẹ̀ wá jẹ́ ọjọ́ mẹ́rin – Àbámẹ́ta, Aìkú, Ajé àti Iṣẹ́gun – tí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyàn r’áàyè jáde wòran dáadáa. Kódà ọ̀pọ̀ ló wá láti ọnà jíjìn àti ìdálẹ̀ láti darapọ̀ mọ́n èrò tó wá bọ̀wọ̀ fú ọba yìí. Onírúirú àrà ní wọ́n dá o! Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọpọ́n àti ọkọ̀-ojú-omi ni wọ́n dárà lórí odò Thames fún ọjọ́ méjì. Elizabeth fúnrarẹ̀ wà nínú ọ̀kan nínú àwọn ọk...