Posts

Showing posts from August, 2019

Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Image
Ẹkú ọjọ́ mẹ́ta o ẹ̀yin ènìà pàtàkì wọ̀nyí. Ṣe dáradára ni mo bá gbogbo yín o? Ọ̀rọ̀ ọ t'òní á fẹ́ jọ yẹ̀yẹ́ létí ẹlòmíì, ṣùgbọ́n kìí ṣ'àwàdà rárá o. Ọ̀rọ̀ gidi ni. Ẹ ní kílódé? Ẹ mà ṣeun o. Ebi ló pa mí ní ìrọ̀lẹ́ òní tó mún mi ya ilé oúnjẹ olókìkí nì tí wọ́n ń pè ní KFC. Adìẹ díndín ni wọ́n ń tà níbẹ̀. 'Tapátẹsẹ̀ ni wọ́n ń dín in. Tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́ ní ẹyọ-ẹyọ, ẹ lè rà á bẹ́ẹ̀. Bó sì jẹ́ àdàpọ̀ ẹsẹ̀ àti apá lẹ fẹ́, ìyẹn náà wà. Kódà wọn a tún máa ṣè'kan pẹlẹbẹ láti igbá-àyà adìẹ, wọ́n á tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ sí ààrin búrẹ́dì pẹ̀lú ẹ̀fọ́ díẹ̀ àti àwọn midinmíìdìn ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Àwọn olóyìnbó a máa pè'yẹn ní "Burger". Kiní ọ̀hún a máa wù'yàn jẹ o jàre. Àgàgà àwọn tí wọ́n fi ata sí dáadáa. Wọ́n tún ṣe'kan tó jọ dùndú anọ̀mọ́ tí wọ́n ń pè ní "fries". Kiní ọ̀hún a máa dùn tí wọ́n bá dín in gbẹ dáadáa. Parí

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Image
Ṣé mo sọ níjọ́sí pé ìfẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bímọ . Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà ọmọ tí wọ́n bí ju ẹyọ kan ṣoṣo lo. Àwọn ọmọ náà ni Ààrùn, Àìsàn, Àìlera àti Àárẹ̀. Àwọn ọmọ wọ̀nyí a máa farahàn ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrà, wọn a sì máa da ọmọ-ènìyàn l'áàmú. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà àrà náà nìwọ̀nyí; Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìfúnpá Gíga, Ìtọ̀ Ṣúgà, Wárápá, Àìsàn Ọkàn, Ọpọlọ Wíwú, Ojú Fífọ́, Ìdákọ́lẹ, Àpọ̀jù Ọ̀rá-Ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Abí ẹ kò rí i pé àjẹjù ṣúgà kò dára fún ọmọ ènìyàn rárá bí? Ó yẹ ká yẹra fún un nígbà gbogbo, kí ó má baà ṣe àkóbá fún wa. Toò, ẹ jẹ́ ká fi man báhun lónìí nítorí pé "ṣókí l'ọbẹ̀ oge". Èmi ni Alákọ̀wé yín ọ̀wọ́n. Ó tún dìgbà kan ná.

Ènìyàn àti Ṣúgà

Image
Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé "a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́". Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé. Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe. Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá. Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo - ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá ày

Ìtẹ̀wé Yorùbá titun gbòde

Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin tèmi. Ó tójọ́ mẹ́ta kan. Ǹjẹ́ ẹ rántí ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, mo ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà kọ èdè Yorùbá pẹ̀lú àmì lórí àwọn ẹ̀rọ wa. Ọ̀nà titun kan ti balẹ̀ wàyí o! Yorubaname.com ni wọ́n fún wa ní ẹ̀bùn yí ní ọ̀fẹ́. Mo ti ń ṣe àmúlò ìtẹ̀wé yìí ní kété tó jáde, kí n lè fún un yín lábọ̀ nípa rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ṣòro ó lò lákọ̀ọ́kọ́, nítorí kò mọ́n mi lára, kò pẹ́ náà tó fi mọ́nra. Kódà, òun ni mò ń lò lọ́wọ́ báyìí. Díẹ̀ nínú àwọn àǹfàní tọ́n hàn sí mi nìwọ̀nyí: 1. Àyè àti fi àmì sí 'n' àti 'm' ( ǹ ń, m̀ ḿ ) 2. Ó ń ṣiṣẹ́ lórí Windows àti Mac 3. Kò l'áàńsí lórí Ayélujára láti ṣiṣẹ́ 4. Ó rọrùn láti lò púpọ̀ ju àwọn ìyókù lọ, tí ó bá ti móni lára tán. 5. Ọ̀fẹ́ ni! Ajẹ́pé ẹ jẹ́ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Yorubaname.com fún akitiyan ńlá yìí. Ó dámi lójú pé èyí kò ní ṣe àṣem

Ata ju ata lọ

Image
Ẹ wá wo orí ológbò látẹ o ẹ̀yin èèyàn mi! "Èwo lẹ tún rí o Alákọ̀wé?" Yó yẹ yín kalẹ́! Mo mà tún rí nkan o. Lóòótọ́ àwa ọmọ Nàìjá a fẹ́ran ata, àgàgà àwa ti ilẹ̀ Oòduà. Ẹlòmíì a se'bẹ̀, a fi ata já a. Kódà a rí ẹni tí kò ní jẹun kankan àfi tí ata bá wà níbẹ̀. Dájú-dájú ìran jata-jata ni àwa ń ṣe. Òun ni mo fi ń yangàn fún àwọn ọ̀rẹ mi kan nílẹ̀ yìí o. Mo wí fún wọn pé kòsí oúnjẹ kankan nílẹ̀ wọn tó láta to tiwa. Mo tún ṣakọ pé irúfẹ́ ata tí èmi Alákọ̀wé ò lè jẹ - wọn kò tí ì ṣẹ̀dá ẹ̀ nílẹ̀ yìí. Àwọn òyìnbó dá mi lóhùn pé òtítọ pọ́nbélé ni mo sọ, n kò parọ́ rárá.   Wọ́n tún wípé kódà àwọn aláwọ̀ funfun tí mo rí yìí - tí àwọn bá ṣèṣì jẹ irú ata tí a ń wí yìí, ńṣe ni ojú àwọn á di pípọ́n kuku bí aṣọ àparò! Bẹ́ẹ̀náàni gbogbo ọ̀nàfun á máa ta àwọn bí ẹní máa kú ni. Wọ́n ní nítorí ìdí èyí ni àwọn kò ṣe kí ń jẹ ata. Pé tí oúnjẹ bá ti láta fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ báyìí, àwọn a yáa yẹra fún un.  Mo rín ẹ̀rín àrínbomilójú nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí tán. Kání àwọn babańlá wa mọ̀n níjọ́ kì

Pàtàkì Ìwé Kíkọ Àti Kíkà Ní Èdè Abínibí

Image
Oun tí a ní là ń náání. Àwọn àgbà Yorùbá ni wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ ní òde òni àwa ọmọ Odùduwà ń náání oun tiwa bí? Ọ̀rọ̀ ọ́ pọ̀ níbẹ̀ o ẹ̀yin ará mi. Ó dáa ẹ jẹ́ ká mú'kan níbẹ̀ ká gbé e yẹ̀wò. Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ràn láti máa sọ èdè Yorùbá lẹ́nu mọ́n, dájú-dájú púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí gbọ́ ọ l'ágbọ̀ọ́yé, wọn kò kàn kí ń sọ ọ́ ni. Lára àwọn agbọ́másọ wọ̀nyí, bóyá la lè rí ìkankan nínú wọn tó mọn èdè Yorùbá kà dáradára, ká tilẹ̀ má sọ̀rọ̀ ọ kíkọ. Àgàgà tí a bá fi àmì sọ́rọ̀, a máa fa ìrújú fún púpọ̀ nínú wọn. Ó mú mi rántí nkan tí ẹnìkan wí lóri Twitter níjọ́sí. Ó ní Yorùbá kíkọ̀ èmi Alákọ̀wé fẹ́ jọ èdè Lárúbáwá lójú òun nítorí àwọn àmì ọ̀rọ̀ tí mo máa ń fi sí i. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún pa mí ní ẹ̀rin lọ́jọ́ náà kì í ṣe díẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ burúkú òhun ẹ̀rín kọ́ rèé ni ẹ̀yin èèyàn mi? À á ti wá gbọ́? Ṣé ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípà èdè Gẹ̀ẹ́sì kíkọ? Ótì o! Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àbí ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Faransé ti ń ránmú sọ Faransé bí? Èmi ò rí i rí o. Kí

Ebola

Image
Mo kí gbogbo yín o. Ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ẹ sì kú àìfaraálẹ̀ náà. Olúwa yó máa fúnwa ní alékún okun àti agbára o. Toò, ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò wá. Èé ti rí? Ọ̀rọ̀ Ebola yìí mà ni o. Kòkòrò búburú tí í fa àjàkálẹ̀ ààrùn. Kòkòrò tí kò gbóògùn. Bóo la ti wá fẹ́ ṣe é o? Ibo là á gbe gbà? Àwọn oní Bókobòko níwá, Èbólà lẹ́hìn. Àfi kí Elédùà kówa yọ. Àmọ́ ṣá, Yoòbá ti wípé ojú l'alákàn fi ń ṣọ́rí. Kí oníkálukú yáa tẹra mọ́n ètò ìmọ́ntótó rẹ̀. Kí ó sì máa ṣe àkíyèsí gbogbo nkan tí ń lọ ní'tòsí. Orísìírísìí là ń gbọ́ nípa kí la lè ṣe láti dáàbò bo'ra ẹni. Àwọn kan ní omi gbígbóná àti iyọ̀ ni ká fi wẹ̀. Kíá ni àti mùsùlùmí àti kìrìstẹ́nì ń da omígbóná ságbárí. A tún gbọ́ pé orógbó tàbí obì ni àjẹsára tọ́n lè báni yẹra fún ààrùn Ebola. Wéré ni tọ́mọ́ndé tàgbà ń rún orógbó lẹ́nu bí i gúgúrú, tí wọ́n sì ń jẹ obì bí ẹní jẹ̀pà. Àt'orógbó àt'obì o, wọn ò ṣé rà lọ́jà mọ́n, ńṣe ni wọ́n gbówó lérí tete. Bẹ́ẹ̀ rèé ènìyàn ò báà bẹ́ sínú àmù ọmígbóná oníyọ̀, kó jẹ́ orógbó agbọ̀n k

Igbó Funfun - Apá kẹta Ìrìnkèrindò Moravia

Image
Mo kúkú tẹnu mọ́n ọn pé Oníyanu ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn, Ó ṣ'èkan ní dúdú aró, ọ̀kan funfun gbòò bí aṣọ àlà. Ẹlòmíì a pọ́n kuku bí aṣọ àparò, Elédùà ló ní kó máa rí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ Aṣèyíṣèmíì ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá igi inú igbó, Ọba Lókè tún dá a bí àrà ọ̀tọ̀. Èyí tó kúrú, èyí tó ga, gbogbo wọn n'ọ́n péjọ sínú igbo, tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára Ẹlẹ́dàá wọn. Òmíì fífẹ̀ gbàràgàdà bí igi osè tó tan gbòngbò kálẹ̀ káàkiri. Àwọn wọ̀nyí kìí ṣábàá ga lọ títí. Yoòbá bọ̀ ó ni "Ẹni bá máa ga, ẹsẹ̀ rẹ̀ yó tínrín" èyí ló dífá fún igi ọ̀pẹ́ nínú igbó. Ẹ jẹ́ ká fi ìyẹn sílẹ̀ ná. Alákọ̀wé Yorùbá, ẹni Olú Ọ̀run dá lọ́lá, mo dé ibi igbó nì tí wọ́n ń pè ní Igbó Funfun. Mo rí iṣẹ́ Ọlọ́run Ọba. Ẹ ní kíni mo rí? Yó yẹ yín o. Ní ọ̀nà àbáwọ igbó náà, àwọn arúgbó igi tò síbẹ̀ wàlàhìhì. Ìtàn fi yé wa pé àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ láti ayé-báyé ni. Àwọ̀ wọn jẹ́ funfun nini, wọn kò sì ní ewé kankan lórí rárá. Wọ́n ní àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ fún bíi ọgọ́rùn-ún mélòóka ọdún. Àgbà igi

Yàrá Inú Òfurufú - àpá kejì Ìrìnkèrindò Moravia

Image
Àwámárìídìí ni Ọlọ́run Ọba. Ẹlẹ́dàá tó dá ayé òun ọ̀run. Alágbára ńlá tó dá àwa ọmọ ènìyàn sórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àgbáyé. Òun náà ló tẹ́ òfurufú léwa lórí. Olódùmarè ló pa á láṣẹ fún òbìrìkìtì ayé kó máa yí oòrùn po láìdúró. Kí ìyípo kan máa jẹ́ ọdún kan. Àní sẹ́, Elédùà Apàṣẹwàá ló ní kí ayé gan-an máa pòyì ararẹ̀. Kí ìpòyì kan máa jẹ́ ọjọ́ kan. Àsẹ Ẹlẹ́dàá ni. Èdùmàrè tó dá ẹ̀dá ọmọ èèyàn tó pàṣẹ pé ká máa bí síi ká sì máa rẹ̀ síi, Òun náa ló ṣe ọpọlọ ọmọ ènìyàn yàtọ̀ sí ti ẹranko lásán. Ó wípé bí ọjọ́ ṣe ń yí lé ọjọ́, tí oṣù ń yí l'óṣù, tí ọdún yí l'ọ́dún, kí ọpọlọ wá náà máa gbòòrò síi. Àlékún ọgbọ́n, àlékún ìmọ̀, àlékún òye ọmọ ènìyàn láti ìrandéran ti mú ìlọsíwájú kànkà bá àwa ọmọ ènìyàn gbáà. Ẹ̀yà ẹranko kan kò jẹ́ rí àwa ọmọ ènìyàn fín, àyàfi tó bá ń wa àbùkù òun ìparun. Àwa ẹ̀dá ọmọ aráyé, a wá dúró gẹ́gẹ́ bí kábiíòsí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá tí Olódùmarè dá sí ilé-ayé. Olódùmarè gbàwá láàyè yìí ká máa dárà bó ti wù wá ní ilé ayé. Kódà àgbára àti làákáyè àwá ọmọ ènìyàn ti

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè

Image
Njẹ́ ibi orí dáni sí làá gbé. Ibi orí ranni lọ làá lọ. Bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ori ránni làá ṣe. Èyí ló fa máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ gbogbo ẹ̀dá. Iṣé òòjọ́ wọn ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀nà àti là yìí náà ni wọ́n ń lépa. Máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ yìí a máa sú ọ̀pọ̀lọpọ̀ dé'bi pé wọn kìí kíyèsí nkan lọ titi lọ́nà ibi tí wọ́n ń lọ. Kí wọ́n ṣáà tètè dé ibiṣẹ́, kí wọ́n tètè parí iṣẹ́, kí wọ́n sì tètè padà dé'lé ló jẹ wọ́n lógún. Bí i tẹ̀mi Alákọ̀wé kọ́. Ní tèmi o, mo máa ń ṣí ojú mi kalẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà ni. Mo sì máa ń ṣe àkíyèsí gbogbo oun tí ń lọ ní àyíká mi. Èmi a máa rí àwọn nkan ìyanu káàkiri gbogbo ilẹ̀ tí mò ń tẹ̀, èmi a sì máa gbé orúkọ́ Ọlọ́run ga. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, n a máa rí ẹwà nínú àwọn nkan kékèké tí àwọn míràn ò kà kún nkankan. Ṣé bó ti wu Elédùà ló ń ṣ'ọlá ẹ̀? Ọba mi a ṣèkan bí àpáta gbànyàyà, Ọba kannáà yìí a ṣe òmíràn bí ọ̀kúta wẹwẹ tí ń bẹ nínú erùpẹ̀. Èdùmàrè yìí tún ṣe iṣẹ́ ẹ̀ l'áṣepé, ó fi làákáyè jíìnkí ọmọ ẹ̀dá. Ó ní ká máa fi ọgbọ́n orí wa dárà ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Irúfẹ

Ojúmọ́ gígùnjùlọ

Image
Àwọn àgbà Yorùbá àtijọ́ a máà sọ̀rọ̀ kan. Wọ́ ní "oòrùn ló ni ọ̀sán, òṣùpá lo ni òru". Òótọ́ ni. Àmọ́ ìyẹn lọ́dọ̀ tíwa lọ́hùún ni o. Ẹ jẹ́ mọ̀n pé àwọn ibìkan ń bẹ tí oòrùn kò ní wọ̀ rárá lónìí? Bẹ́ẹ̀ni. Ajẹ́pé lọ́dọ̀ tiwọn níbẹ̀, àti ọ̀sán gan-gan o, àti gànjọ́ òru, ìkáwọ́ oòrùn ló wà. Ìyẹn lórí eèpẹ̀ àgbálá ayé wa yìí náà o. Ní ìlú ọba níhìín, fún wákàtí mẹ́rìndínlógún àti ìṣẹ́jú méjìdínlógójì ni oòrùn yíò ran ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ yanyanyan léwa lórí kó tó wọ̀ ni nkan bí i aago mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún. Aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni mo ya àwòrán yìí lónìí, àmọ́ ẹ wo bí oòrùn ti mún. Kódà ní ìta gbangba ńṣe ni oòrùn kanni látàrí gbọ̀ngbọ̀n. Ìdí abájọ ni pé òní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje ọdún ni ojúmọ́ gígùnjùlọ lọ́dún ní ìhà àríwá àgbáyé. Mo ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí rí níbìkan . Òní tún bọ́ sí ọjọ́ Àbámẹ́ta tí í ṣe ọjọ́ ìgádùn kẹlẹlẹ. Ní tèmi Alákọ̀wé, fàájì ni mo wà o jàre.

Ìrìnkèrindò Moravia

Image
Yoòbá ní àìrìnjìnnà ni kò jẹ́ ká rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Ẹ wo ibi Alákọ̀wé rìn dé tó fi rí abuké erin. Ìrìnkèrindò gidi rèé o, ẹ máa bá mi kálọ. Ilẹ̀ kan ń bẹ láàrin gbùgbùn Úróòpù tí ń jẹ́ Moravia. Ilẹ̀ ọ̀hún kìkì òkè ni, ó sì kún fún àwọn igbó aginjù ńlá-ńlá àti adágún odò fífẹ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Èmi Alákọ̀wé yín àtàtà, mo fi ẹsẹ̀ mi méjéèjì tí Elédùà fún mi rin àwọn òkè náà. Mo sọdá àwọn odò tí wọn kò jìn púpọ̀jù, mo sì rìn nínú àwọn igbó wọnnì pẹ̀lú. Ó wá ṣe bí ẹni pé èmi gan-an ni ògbójú ọdẹ nínú igbó Maravia. Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé bíótilẹ̀jẹ́pé mo rí àwọn ẹranko kọ̀ọ̀kan t'ọ́n ṣàjèjì sí mi, n kò fojú kan ẹbọra tàbí abàmì ẹdá kankan o :) . Ọpẹ́ ni fún Olódùmarè. Àmọ́ ṣá, oríṣìíríṣìí lojú rí níbẹ̀ o. Nígbàtí mo dé ẹ̀bá igbó kan, mo ṣàdédé rí nkan tó jọ agbárí ìkookò tí ẹnìkan gbé kọ́ igi. Ó dẹ́ru báni púpọ̀. Nígbà tó tún ya mo tún ń wo nkankan lókèrè tó fẹ jọ òjòlá ńlá. Ó kù díẹ̀ kí n padà lọ́nà kí n tó rí i pé okun lásán ni mo rí. Oríta mẹ́ta kan ń bẹ lọ́nà àbáwọ

Àwọn Omi Sulis

Image
Ẹni tó wípé Alákọ̀wé ìwọ dà láti'jọ́ yìí? Ó mà ṣe fírífírí kẹ̀. Enítọ̀hún ṣeun aájò wa jàre. Àṣá ò pẹ́ lóko bẹ́ẹ̀ rí ọ̀nà ló pọ̀ Ìrìnàjò mà ni Alákọ̀wé tẹsẹ̀ bọ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan o. Mo dé ìhà ìlà-oòrùn àgbáyé níbi tí ọjọ́ ti ń kọ́kọ́ mọ́n. Mo dé ìwọ̀-oòrùn níbi tí agbami òkun ti lọ kánrin-kése kọ́já ibi ojú rí. Àní mo dé àríwá ayé níbi yìnyín gbé rọ̀ dàálẹ̀ bí òjò. Gúsù ńkọ́? Níbi oòrùn ti ń yọ lóru gànjọ́, gbogbo rẹ̀ ló sojú èmi kinní yìí. Ìlé-ayé yìí kún fún nkan àdìtú àti ìyanu. Ìrìn gbé mi dé ìlú kan tí ń jẹ́ Bath. Orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ìlú náà wà. Nkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ṣẹ́hìn ni wọ́n tẹ ìlú náà dó sí etí odò Avon. Àwọn ará Róòmù tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ dó sọ ọ́ lórúkọ 'Aquae Sulis' (Àwọn Omi Sulis). Òrìṣà ayé-àtijọ́ kan nílẹ̀ yìí ni ó ń jẹ́ Sulis. Àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n wà níbẹ̀ kí àwọn Gẹ̀ẹ́sì tó dé ni wọ́n ń bọ òrìṣà náà nígbà náà. Ìdí tí wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Aquae Sulis ni pé sẹ́lẹ̀ru omi gbígbóná kan wà níbẹ̀ tí wọ́n gbàgbọ́ pé a máa wo aláìsàn sàn

Omi

A kìí bómi ṣọ̀tá - ó ṣèwọ̀. Ṣé omi làbùwẹ̀, òun làbùmu. Jíjí tí mo jí ní kùtù-kùtù, omi ni mo fi bọ́jú, òun ni mo fi fọnu. Mo tọ orílẹ̀ yìí dé ìpẹ̀kun àríwá mo kan agbami òkun àwòyó ni ń bẹ ní gúsù. Njẹ́ orí rẹ làá tí tu'pọ́n inú rẹ ni tọmọdé tàgbà ti ń játùbú. Kòṣémánìí ni ọ́ omi Ìwọ gan-an ni kòríkòsùn àrin òru Orí rẹ ni Olódùmarè tẹ́ ilé-ayé lé Ẹni fojú di ọ́, olúwarẹ̀ kàbùkù. Ṣé ìwọ lọ̀ ń bẹ nínú ìtọ̀, ìwọ lọ̀ ń bẹ nínú itọ́ ìwọ ni omijé ti inú ẹyinjú Orí mi má mà jẹ́ n pàdánù omi Kòsí oun tí ń gbani lọ́wọ́ omi àfi ikú.

Fìlà wo?

Image
Yoòbá ní a rí ẹni tó lórí tí kò ní fìlà, a r'ẹ́ni tó ní fìlà tí kò lórí. Lọ́lá Ọlọ́run Ọba, a r'ẹ́ni tó lórí kẹ̀dẹ̀rẹ̀-kẹdẹrẹ, tó tún kó fìlà jọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Irúfẹ́ enítọ̀hún ni Alákọ̀wé yín. Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa ló fi fún mi kìí ṣe ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ o, ṣèbí bí a ó ba wọ fìlà, dandan ni kó bá aṣọ mu. Àfi tí ènìyàn bá fẹ́ fi'rarẹ̀ wọ́lẹ̀ ní àwùjọ. Ṣé ẹ mọ̀n tẹ́lẹ̀ pé ará oko ni èmi jẹ́. Èmi ò mọn kíni fáàrí tí ń lọ lóde. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará èkó ti máa ń wí fún mi -"o ò damọ̀". :) Toò. Yoòbá bọ̀ wọ́n ní "Ajá ìwòyí là ń lé sí ehoro ìwòyí". Ajẹ́pé ẹ̀yin olólùfẹ́ alákọ̀wé.com àti òntẹ̀lé @alakoweyoruba ni màá bẹ̀ sọ́rọ̀ yí o. Ẹ dákun fìlà wo ló ba aṣọ yìí mu jùlọ? Ati pé èwo níbẹ̀ lo wuyì jù? Ẹ yáa tètè fún mi l'ésì o, nítorí òde tí mò ń lọ náà, àrin àwọn onífáàrí gidi ni.

Iṣẹ́ ló ń ṣíwájú ìgbádùn

Image
Wọ́n ní ẹni tó da omi sí'wájú, ẹnítọ̀hún yó tẹ ilẹ̀ tútù. Ìyẹn ni pé kí a tó jẹ ìgbádùn, iṣẹ́ ní í ṣíwájú ẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí ló díá f'Álákọ̀wé lọ́jọ́ òní. Njẹ́ ẹni tó fẹ́ jẹ ọbẹ̀ ilá yíò kọ́kọ́ rẹ́'lá. Àbí ẹni tó fẹ jẹ àmàlà, kí ìgùnwọ́ olúwarẹ̀ yáa gbáradì nítorí ọmọrogùn àti ìkòkò ọkà wọn kìí ṣ'ọ̀rẹ́ arawọn. Àmọ́ o, ẹni tó bá tẹra mọ́n'ṣẹ́, ó di dandan kó jẹ̀rè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Bótiwù kó roni lójú láti rẹ́ ilá, tàbí láti ro àmàlà, tí oúnjẹ bá dé'lẹ̀ tán ìgbádùn dé! Ẹkú ìsinmi òní o. Ẹ bá mi're :)

Àdìtú Stonehenge

Image
Ní ìyálẹ̀ta ọjọ́ òní ni àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí ti jí dé ibi àkójọpọ̀ okúta ayérayé nì tí wọ́n ń pè ní Stonehenge. Ìdí abájọ ni pé lọ́jọ́ òní, tí í ṣe ọjọ́dọ́gba, ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé. Ìyẹn ni pé ìgbà ọ̀gìnìntìn ti ré kọjá, a ti bọ́ sí ìgbà ọ̀tun. Ní ayé àtijọ́ kí ẹ̀sin Kìrìstẹ́nì tó dé'lẹ̀ yìí, àwọn náà ní ẹ̀sìn ìbílẹ̀ tiwọn. Ọ̀kan nínú àwọn àjọ̀dún tó rọ̀ mọ́n ẹ̀sìn náà ni àjọ̀dún òrìṣà Eostre. Eostre ni òrìṣà nkan tuntun, ìgbà tuntun, bí ọmọ bíbí. Ìdí èyí ni a fi rí orúkọ abo òrìṣà yìí nínu "E(o)strogen" fún àpẹrẹ. Ẹ ka nkan tí mo kọ nípa Eostre àti Easter Stonehenge ti pẹ́ ní orílẹ̀ yìí tó jẹ́ pé a kò lè sọ pàtó pé àwọn báyìí ni wọ́n kọ́ ọ síbẹ̀. Orísìíríṣìí ìtàn atẹnudẹ́nu ló dárúkọ rẹ̀, àmọ́ kòsí ẹni tó mọn òdodo ọ̀rọ̀. Bótiwù kó jẹ́, nkan ìyanu gidi ni òkuta yìí. Lọ́jọ́ òní, àti lọ́jọ́dọ́gba ìgbà ìwọ́wé, ìlànà tí oòrùn tọ̀ láti ilà dé ìwọ̀ lókè ọ̀run bá ti Stonehenge mu rẹ́gí-rẹ́gí nílẹ̀. Èyí fi hàn wá pé làákáyè ńlá ni àwọn tí wọ́n kọ́ ọ ní.