Oúnjẹ Àárọ̀ Ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Ọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa oúnjẹ àárọ̀ tí wọ́n máa ń jẹ ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Pàápàá jùlọ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ọjọ́ ìsinmin àbámẹ́ta àti àìkú. Ìyen ni òpin ọ̀sẹ̀ tí kò l’áàánsáré jẹun kí a le tètè jáde nílé lọ ibiṣẹ́ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
N kò lè s’àì mẹ́nuba oúnjẹ oní kíákíá tí ó wọ́pọ̀ láti jẹ lọ́jọ́ ọ̀sẹ̀. Èyí tó wọ́pọ̀ jùlọ ni kiní kan tí wọ́n fi àgbàdo àbí ọkà-bàbà ṣe tí wọ́n ń pè ni cornflakes. Bí wọ́n ti ń jẹ oúnjẹ àgbàdo yìí lèyìí. Wọ́n a dàá sí inú àwo, wọ́n a sì da wàrà tútù lé e. Òmíràn nínú àwọn oújẹ àgàdo yìí ni wọ́n á ti fi ṣúgà tàbí oyin àti onírúirú nǹkan aládùn pa lára. Ṣùgbọ́n òmíràn a máa jẹ́ gberefu.
Nígbàmíràn tí kò bá si oúnjẹ nílé, wọ́n a máa ra oúnjẹ àárọ̀ aláràjẹ lọ́nà. l’áràárọ̀ ni èrò máa ń tò síwájú àwọn ilé oúnjẹ wọ́nyìí tí wọ́n sì njẹ àjẹrìn dé ibiṣẹ́.
Eléyìí tí wọ́n ń farabalẹ̀ jẹ, tí wọ́n sì fẹ́ràn gidi jùlọ ni wọ́n ń pè ní Ọúnjẹ Àárọ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Oúnjẹ yìí lékenkà tóbẹ́ẹ̀gẹ́ ó sì jẹ́ nǹkan ìwúrí fún orílẹ̀èdè yìí. Orísìírísìí ẹ̀yà oúnjẹ yìí ni ó wà. Ṣùgọ́n ìyẹn di ọwọ́ ẹni tó ń jẹun. Èròjà tí ènìà bá fẹ́ ni ènìàn ń fi sí i. Bẹ́ẹ̀náàni èyí tí ènìà bá kórira, kò fa dandan. Díndín ni, bíbọ̀ ni, yíyan ni, gbogbo rẹ̀ á péjọ lórí abọ́ á máa ṣọ̀rá sìnkìn.
Díẹ̀ nínú àwọn èròjà ọ̀hún rèé:
Ẹyin díndín
Ẹyin bíbọ̀
Ẹ̀wà inú agolo
Esusun
Tìmáàtì
Ẹran ẹlẹ́dẹ̀ díndín
Ànànmán díndín (ó dàbí dùndú)
Búrẹ́dì gbẹrẹfu tàbí yíyan
Tíì àbí kọfí.
Omi ọsàn tàbí òrombó
Comments
Post a Comment